Isa 7:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitoripe, ki ọmọ na ki o to mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire, ilẹ ti iwọ korira yio di ikọ̀silẹ lọdọ ọba rẹ̀ mejeji.

17. Oluwa yio si mu ọjọ ti kò si bẹ̃ ri wá sori rẹ ati sori awọn enia rẹ, ati sori ile baba rẹ, lati ọjọ ti Efraimu ti lọ kuro lọdọ Juda, ani ọba Assiria.

18. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio kọ si eṣinṣin ti o wà li apa ipẹkun odo ṣiṣàn nlanla Egipti, ati si oyin ti o wà ni ilẹ Assiria.

19. Nwọn o si wá, gbogbo wọn o si bà sinu afonifojì ijù, ati sinu pàlapala okuta, ati lori gbogbo ẹgun, ati lori eweko gbogbo.

20. Li ọjọ kanna ni Oluwa yio fi abẹ ti a yá, eyini ni, awọn ti ihà keji odo nì, ọba Assiria, fá ori ati irun ẹsẹ, yio si run irungbọn pẹlu.

Isa 7