14. Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli.
15. Ori-amọ ati oyin ni yio ma jẹ, ki o le ba mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire.
16. Nitoripe, ki ọmọ na ki o to mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire, ilẹ ti iwọ korira yio di ikọ̀silẹ lọdọ ọba rẹ̀ mejeji.
17. Oluwa yio si mu ọjọ ti kò si bẹ̃ ri wá sori rẹ ati sori awọn enia rẹ, ati sori ile baba rẹ, lati ọjọ ti Efraimu ti lọ kuro lọdọ Juda, ani ọba Assiria.
18. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio kọ si eṣinṣin ti o wà li apa ipẹkun odo ṣiṣàn nlanla Egipti, ati si oyin ti o wà ni ilẹ Assiria.