Isa 66:19-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.

20. Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa.

21. Ninu wọn pẹlu li emi o si mu ṣe alufa ati Lefi; li Oluwa wi.

22. Nitori gẹgẹ bi awọn ọrun titun, ati aiye titun, ti emi o ṣe, yio ma duro niwaju mi, bẹ̃ni iru-ọmọ rẹ ati orukọ rẹ yio duro, li Oluwa wi.

23. Yio si ṣe, gbogbo ẹran-ara yio si wá tẹriba niwaju mi, lati oṣù titun de oṣù titun, ati lati ọjọ isimi de ọjọ isimi, li Oluwa wi.

Isa 66