16. Nitori Oluwa yio fi iná ati idà rẹ̀ ṣe idajọ gbogbo ẹran-ara; awọn okú Oluwa yio si pọ̀.
17. Awọn ti o yà ara wọn si mimọ́, ti nwọn si sọ ara wọn di mimọ́ ninu agbala wọnni, ti ọkan tẹle ekeji li ãrin, nwọn njẹ ẹran ẹlẹdẹ, ati ohun irira, ati eku, awọn li a o parun pọ̀; li Oluwa wi.
18. Nitori emi mọ̀ iṣẹ ati ìro wọn: igba na yio dé lati ṣà gbogbo awọn orilẹ-ède ati ahọn jọ, nwọn o si wá, nwọn o si ri ogo mi.
19. Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.