Isa 50:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si.

7. Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi.

8. Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi.

9. Kiye si i, Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ, tani o dá mi li ẹbi? wò o, gbogbo wọn o di ogbó bi ẹwù; kokòro yio jẹ wọn run.

10. Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀.

11. Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.

Isa 50