Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.