Isa 48:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala.

11. Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.

12. Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin.

13. Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.

14. Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea.

15. Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde.

16. Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi.

17. Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ.

Isa 48