Isa 32:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ibi ni gbogbo ohun-elò enia-kenia jẹ pẹlu: on gbà èro buburu, lati fi ọ̀rọ eke pa talaka run, bi alaini tilẹ nsọ õtọ ọ̀rọ.

8. Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.

9. Dide, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; gbọ́ ohùn mi, ẹnyin alafara obinrin; fetisi ọ̀rọ mi.

10. Ọpọlọpọ ọjọ, on ọdún, li a o fi ma wahala nyin, ẹnyin alafara obinrin: nitori ikore kì yio si, kikojọ rẹ̀ kì yio de.

11. Warìri, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; ki wahala ba nyin ẹnyin alafara: ẹ tú aṣọ, ki ẹ si wà ni ihòho, ki ẹ si dì àmure ẹgbẹ́ nyin.

12. Nwọn o pohùnrere fun ọmú, fun pápa daradara, ati fun àjara eleso.

13. Ẹgún ọ̀gan on òṣuṣu yio wá sori ilẹ awọn enia mi; nitõtọ, si gbogbo ile ayọ̀ ni ilu alayọ̀.

14. Nitoripe a o kọ̀ ãfin wọnni silẹ; a o fi ilu ariwo na silẹ; odi ati ile-iṣọ́ ni yio di ihò titi lai, ayọ̀ fun kẹtẹkẹ́tẹ-igbẹ, pápa-oko fun ọwọ́-ẹran;

15. Titi a o fi tú Ẹmi jade si wa lara lati oke wá, ati ti aginju yio fi di ilẹ eléso, ti a o si kà ilẹ eleso si bi igbo.

16. Nigbana ni idajọ yio ma gbe aginju; ati ododo ninu ilẹ eleso.

17. Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ãbo titi lai.

Isa 32