1. EGBE ni fun Arieli, fun Arieli, ilu ti Dafidi ti ngbe! ẹ fi ọdun kún ọdun; jẹ ki wọn pa ẹran rubọ.
2. Ṣugbọn emi o pọ́n Arieli loju, àwẹ on ibanujẹ yio si wà; yio si dabi Arieli si mi.
3. Emi o si dótì ọ yika, emi o si wà odi tì ọ, emi o si mọ odi giga tì ọ.
4. A o si rẹ̀ ọ silẹ, iwọ o sọ̀rọ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio rẹ̀lẹ lati inu ekuru wá, ohùn rẹ yio si dabi ti ẹnikan ti o li ẹmi àfọṣẹ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio si dún lati inu erupẹ ilẹ wá.
5. Ọpọlọpọ awọn ọtá rẹ yio dabi ekuru lẹ́bulẹ́bu, ọpọlọpọ aninilara rẹ yio dabi ìyangbo ti o kọja lọ: lõtọ, yio ri bẹ̃ nisisiyi lojiji.
6. Ãrá, ìṣẹlẹ, ati iró nla, pẹlu ìji on ẹfúfu, ati ọwọ́ ajonirun iná ni a o fi bẹ̀ ọ wò lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá.
7. Bi alá iran oru li ọ̀pọlọpọ awọn orilẹ-ède ti mba Arieli jà yio ri; gbogbo ẹniti o bá ati on, ati odi agbara rẹ̀ jà, ti nwọn si pọ́n ọ loju.
8. Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà.
9. Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile.
10. Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju.
11. Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.
12. A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe.