Isa 24:12-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.

13. Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán.

14. Nwọn o gbe ohùn wọn soke, nwọn o kọrin nitori ọla-nla Oluwa, nwọn o kigbe kikan lati okun wá.

Isa 24