Isa 24:11-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Igbe fun ọti-waini mbẹ ni igboro; gbogbo ayọ̀ ṣú òkunkun, aríya ilẹ na lọ.

12. Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.

13. Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán.

Isa 24