3. Gbogbo ẹnyin ti ngbe aiye, ati olugbé aiye, ẹ wò, nigbati on gbe ọpagun sori awọn oke giga; ati nigbati on fọn ipè, ẹ gbọ́.
4. Nitori bẹ̃li Oluwa sọ fun mi, emi o simi, emi o si gbèro ninu ibugbé mi, bi oru ọsángangan, ati bi awọsanma ìri, ninu oru ikorè.
5. Nitori ṣaju ikorè, nigbati ìrudi ba kún, ti itanná ba di eso-àjara pipọn on o fi dojé rẹ́ ẹka-titun, yio si mu kuro, yio si ke ẹka lu ilẹ.