2. Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni.
3. Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn.
4. Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ.
5. Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán.