Isa 15:5-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.

6. Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.

7. Nitorina ọ̀pọ eyi ti nwọn ti ni, ati eyi ti nwọn ti kojọ, ni nwọn o gbe kọja odò willo.

8. Nitori igbe na ti yi agbegbè Moabu ka; igbe na si de Eglaimu, ati igbe na de Beerelimu.

Isa 15