Isa 10:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ãke ha le fọnnu si ẹniti nfi i la igi? tabi ayùn ha le gbe ara rẹ̀ ga si ẹniti nmì i? bi ẹnipe ọgọ le mì ara rẹ̀ si awọn ti o gbe e soke, tabi bi ẹnipe ọpa le gbe ara rẹ̀ soke, bi ẹnipe ki iṣe igi.

16. Nitorina ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio mu awọn tirẹ̀ ti o sanra di rirù: ati labẹ ogo rẹ̀ yio da jijo kan bi jijo iná.

17. Imọlẹ Israeli yio si jẹ iná, ati Ẹni-Mimọ́ rẹ̀ yio jẹ ọwọ́-iná: yio si jo ẹgún ati ẹwọn rẹ̀ run, li ọjọ kan;

18. Yio si jo ogo igbó rẹ̀ run, ati oko rẹ̀ ẹlẹtù loju, ati ọkàn ati ara: nwọn o si dabi igbati ọlọpagun ndakú.

19. Iyokù igi igbó rẹ̀ yio si jẹ diẹ, ti ọmọde yio le kọwe wọn.

20. Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ.

21. Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara.

22. Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo.

Isa 10