Ọwọ́ mi si ti wá ọrọ̀ awọn enia ri bi itẹ ẹiyẹ: ati gẹgẹ bi ẹnipe ẹnikan nko ẹyin ti o kù, li emi ti kó gbogbo aiye jọ; kò si ẹniti o gbọ̀n iyẹ, tabi ti o ya ẹnu, tabi ti o dún.