Nitori o wipe, nipa agbara ọwọ́ mi ni emi ti ṣe e, ati nipa ọgbọ́n mi; nitori emi moye, emi si ti mu àla awọn enia kuro, emi si ti ji iṣura wọn, emi si ti sọ awọn ará ilu na kalẹ bi alagbara ọkunrin.