22. Fadaka rẹ ti di ìdarọ́, ọti-waini rẹ ti dà lu omi:
23. Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.
24. Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.
25. Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro:
26. Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ.
27. Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo.