8. Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi,
9. Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun.
10. Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun.
11. Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè:
12. Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa.
13. Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.
14. Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ.