2. Sam 1:21-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a.

22. Ọrun Jonatani ki ipada, ati idà Saulu ki ipada lasan lai kan ẹjẹ awọn ti a pa, ati ọra awọn alagbara.

23. Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ.

24. Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ́ wọ̀ nyin, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara aṣọ nyin.

25. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu larin ogun! A Jonatani! iwọ ti a pa li oke giga rẹ!

26. Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obinrin lọ.

27. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!

2. Sam 1