12. Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu.
13. Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe.
14. Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa?
15. Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú.
16. Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.
17. Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀: