4. O si wipe, Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ọwọ rẹ̀ mu eyi ti o ti fi ẹnu rẹ̀ sọ fun Dafidi baba mi ṣẹ, wipe,
5. Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi:
6. Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi.
7. O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli:
8. Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ.
9. Sibẹ iwọ kò gbọdọ kọ́ ile na; ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio jade ti inu rẹ wá ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.
10. Oluwa si ti mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ; emi si dide ni ipò Dafidi baba mi, a si gbé mi ka itẹ́ Israeli bi Oluwa ti ṣe ileri, emi si ti kọ́ ile na fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli.
11. Ati ninu rẹ̀ ni mo fi apoti-ẹri na si, ninu eyiti majẹmu Oluwa wà, ti o ba awọn ọmọ Israeli dá.
12. On si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ ọwọ rẹ̀ mejeji.
13. Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun,