2. Kro 6:39-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wá, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si mu ọ̀ran wọn duro, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn enia rẹ jì ti nwọn ti da si ọ.

40. Nisisiyi Ọlọrun mi, jẹ ki oju rẹ ki o ṣí, ki o si tẹtisilẹ si adura si ihinyi.

41. Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire.

42. Oluwa Ọlọrun, máṣe yi oju ẹni ororo rẹ pada: ranti ãnu fun Dafidi, iranṣẹ rẹ.

2. Kro 6