12. On si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ ọwọ rẹ̀ mejeji.
13. Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun,
14. O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ li ọrun tabi li aiye: ti npa majẹmu mọ́, ati ãnu fun awọn iranṣẹ rẹ, ti nfi tọkàntọkan wọn rìn niwaju rẹ.
15. Iwọ ti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi baba mi, pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́; ti iwọ si ti fi ẹnu rẹ sọ, ti iwọ si ti fi ọwọ rẹ mu u ṣẹ, bi o ti ri loni yi.
16. Njẹ nisisiyi, Oluwa, Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́, wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ́ Israeli: kiki bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati ma rìn ninu ofin mi, bi iwọ ti rìn niwaju mi.