1. NIGBANA ni Solomoni wipe, Oluwa ti wipe, on o ma gbe inu òkunkun biribiri.
2. Ṣugbọn emi ti kọ́ ile ibugbe kan fun ọ, ati ibi kan fun ọ lati ma gbe titi lai.
3. Ọba si yi oju Rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli; gbogbo ijọ awọn enia Israeli si dide duro.
4. O si wipe, Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ọwọ rẹ̀ mu eyi ti o ti fi ẹnu rẹ̀ sọ fun Dafidi baba mi ṣẹ, wipe,
5. Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi:
6. Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi.
7. O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli: