2. Kro 5:8-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃ni awọn kerubu nà iyẹ wọn bò ibi apoti-ẹri na, awọn kerubu si bò apoti-ẹri na, ati awọn ọpa rẹ̀ lati òke wá.

9. Ọpa rẹ̀ wọnni si gùn tobẹ̃, ti a fi ri ori awọn ọpa na lati ibi apoti-ẹri na niwaju ibi mimọ́-jùlọ na, ṣugbọn a kò ri wọn li ode. Nibẹ li o si wà titi di oni yi.

10. Kò si ohun kan ninu apoti-ẹri na bikòṣe walã meji ti Mose fi sinu rẹ̀ ni Horebu, nigbati Oluwa fi ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti Egipti jade wá.

11. O si ṣe, nigbati awọn alufa ti ibi mimọ́ jade wá; (nitori gbogbo awọn alufa ti a ri li a yà si mimọ́, nwọn kò si kiyesi ipa wọn nigbana:

2. Kro 5