2. Kro 34:25-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀.

26. Bi o si ṣe ti ọba Juda nì, ẹniti o rán nyin lati bère lọwọ Oluwa, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:

27. Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun, nigbati iwọ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ si ihinyi, ati si awọn ti ngbe ibẹ, ti iwọ si rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi, ti iwọ si fa aṣọ rẹ ya, ti iwọ si sọkun niwaju mi; ani emi ti gbọ́ tirẹ pẹlu, li Oluwa wi.

28. Kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ si isa-okú rẹ li alafia, bẹ̃ni oju rẹ kì yio ri gbogbo ibi ti emi o mu wá si ihinyi, ati sori awọn ti ngbe ibẹ. Bẹ̃ni nwọn mu èsi pada fun ọba wá.

2. Kro 34