12. Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀?
13. Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara?
14. Tani ninu gbogbo awọn oriṣa orilẹ-ède wọnni, ti awọn baba mi parun tũtu, ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ti Ọlọrun nyin yio fi le gbà nyin lọwọ mi?
15. Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?
16. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ jù bẹ̃ lọ si Oluwa Ọlọrun, ati si iranṣẹ rẹ̀, Hesekiah.
17. O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi.