2. Kro 32:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN ti a ti ṣe iṣẹ wọnyi lotitọ, Sennakeribu, ọba Assiria, de, o si wọ̀ inu Juda lọ, o si dótì awọn ilu olodi, o si rò lati gbà wọn fun ara rẹ̀.

2. Nigbati Hesekiah ri pe Sennakeribu de, ti o fi oju si ati ba Jerusalemu jagun,

3. O ba awọn ijoye rẹ̀ ati awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ gbìmọ, lati dí omi orisun wọnni, ti mbẹ lẹhin ilu: nwọn si ràn a lọwọ.

4. Bẹ̃li ọ̀pọlọpọ enia kojọ pọ̀, awọn ẹniti o dí gbogbo orisun, ati odò ti nṣàn la arin ilẹ na ja, wipe, Nitori kili awọn ọba Assiria yio ṣe wá, ki nwọn ki o si ri omi pupọ̀?

5. O mu ara rẹ̀ le pẹlu, o si mọ gbogbo odi ti o ti ya, o si gbé e ga de awọn ile-iṣọ, ati odi miran lode, o si tun Millo ṣe ni ilu Dafidi, o si ṣe ọ̀kọ ati apata li ọ̀pọlọpọ.

2. Kro 32