2. Kro 31:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi.

11. Nigbana ni Hesekiah paṣẹ lati pèse iyàrá-iṣura ni ile Ọlọrun; nwọn si pèse wọn.

12. Nwọn si mu awọn ọrẹ ati idamẹwa ati ohun ti a yà si mimọ́ wọ̀ ile wá nitõtọ: lori eyiti Kononiah, ọmọ Lefi, nṣe olori, Ṣimei arakunrin rẹ̀ si ni igbakeji.

13. Ati Jehieli, ati Asasiah, ati Nahati, ati Asaheli, ati Jerimoti, ati Josabadi, ati Elieli, ati Ismakiah, ati Mahati, ati Benaiah, ni awọn alabojuto labẹ ọwọ Kononiah ati Ṣimei arakunrin rẹ̀, nipa aṣẹ Hesekiah ọba, ati Asariah, olori ile Ọlọrun.

14. Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ.

15. Ati labẹ ọwọ rẹ̀ ni Edeni, ati Miniamini, ati Jeṣua, ati Ṣemaiah, Amariah, ati Ṣekaniah, ninu ilu awọn alufa, lati fun awọn arakunrin wọn li ẹsẹsẹ, li otitọ, bi fun ẹni-nla, bẹ̃ni fun ẹni-kekere.

2. Kro 31