8. Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin.
9. Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀.
10. Bẹ̃ li awọn onṣẹ na kọja lati ilu de ilu, ni ilẹ Efraimu ati Manasse titi de Sebuluni: ṣugbọn nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wọn.
11. Sibẹ omiran ninu awọn enia Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rẹ̀ ara wọn silẹ, nwọn si wá si Jerusalemu.
12. Ni Judah pẹlu, ọwọ Ọlọrun wà lati fun wọn li ọkàn kan lati pa ofin ọba mọ́ ati ti awọn ijoye, nipa ọ̀rọ Oluwa.
13. Ọ̀pọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalemu, lati pa ajọ akara alaiwu mọ́ li oṣu keji, ijọ enia nlanla.