11. Sibẹ omiran ninu awọn enia Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rẹ̀ ara wọn silẹ, nwọn si wá si Jerusalemu.
12. Ni Judah pẹlu, ọwọ Ọlọrun wà lati fun wọn li ọkàn kan lati pa ofin ọba mọ́ ati ti awọn ijoye, nipa ọ̀rọ Oluwa.
13. Ọ̀pọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalemu, lati pa ajọ akara alaiwu mọ́ li oṣu keji, ijọ enia nlanla.
14. Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni.