1. SOLOMONI si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu li òke Moriah nibiti Ọlọrun farahàn Dafidi baba rẹ̀, ti Dafidi ti pèse, nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.
2. On si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile ni ọjọ keji oṣù keji, li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀.
3. Eyi si ni ìwọn ti Solomoni fi lelẹ fun kikọ́ ile Ọlọrun. Gigùn rẹ̀ ni igbọnwọ gẹgẹ bi ìwọn igbãni li ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ.
4. Ati iloro ti mbẹ niwaju ile na, gigùn rẹ̀ ri gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgọfa; o si fi kiki wura bò o ninu.