6. Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju Oluwa Ọlọrun wa, nwọn si ti kọ̀ ọ silẹ, nwọn si ti yi oju wọn pada kuro ni ibugbe Oluwa, nwọn si ti pa ẹhin wọn da.
7. Nwọn ti tì ilẹkun iloro na pẹlu, nwọn si ti pa fitila, nwọn kò si sun turari, bẹ̃ni nwọn kò ru ẹbọ sisun ni ibi mimọ́ si Ọlọrun Israeli.
8. Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri.
9. Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi.