23. Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori.
24. Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli.
25. O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀.
26. Awọn ọmọ Lefi si duro pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ati awọn alufa pẹlu ipè.
27. Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli.
28. Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.
29. Nigbati nwọn si ṣe ipari ẹbọ riru, ọba ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ tẹ̀ ara wọn ba, nwọn si sìn.
30. Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn.
31. Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá.
32. Iye ẹbọ sisun, ti ijọ enia mu wá, si jẹ ãdọrin akọ-malu, ati ọgọrun àgbo, ati igba ọdọ-agutan: gbogbo wọnyi si ni fun ẹbọ-sisun si Oluwa.
33. Awọn ohun ìyasi-mimọ́ si jẹ ẹgbẹta malu, ati ẹgbẹdogun agutan.
34. Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́.
35. Ati pẹlu, awọn ẹbọ sisun papọju, pẹlu ọra ẹbọ-alafia, pẹlu ẹbọ ohun-mimu fun ẹbọ sisun. Bẹ̃li a si to iṣẹ́-ìsin ile Oluwa li ẹsẹsẹ.
36. Hesekiah si yọ̀, ati gbogbo enia pe, Ọlọrun ti mura awọn enia na silẹ: nitori li ojiji li a ṣe nkan na.