2. Kro 28:22-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ati li akokò ipọnju rẹ̀, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa. Eyi ni Ahasi, ọba.

23. Nitori ti o rubọ si awọn oriṣa Damasku, awọn ẹniti o kọlù u: o si wipe, Nitoriti awọn oriṣa awọn ọba Siria ràn wọn lọwọ, nitorina li emi o rubọ si wọn, ki nwọn le ràn mi lọwọ. Ṣugbọn awọn na ni iparun rẹ̀ ati ti gbogbo Israeli.

24. Ahasi si kó gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun jọ, o si ké kuro lara ohun-elo ile Ọlọrun, o si tì ilẹkun ile Oluwa, o si tẹ́ pẹpẹ fun ara rẹ̀ ni gbogbo igun Jerusalemu.

25. Ati ni gbogbo orori ilu Juda li o ṣe ibi giga wọnni, lati sun turari fun awọn ọlọrun miran, o si mu Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀ binu.

26. Ati iyokù iṣe rẹ̀, ati ti gbogbo ọ̀na rẹ̀ ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.

2. Kro 28