18. Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ.
19. Nitoriti Oluwa ti rẹ̀ Juda silẹ nitori Ahasi, ọba Juda: nitoriti o mu Juda di alaini iranlọwọ, o si ṣe irekọja gidigidi si Oluwa.
20. Tilgati-pilnesari, ọba Assiria, si tọ̀ ọ wá, ọ si pọn ọ loju, ṣugbọn kò fun u li agbara.
21. Ahasi sa kó ninu ini ile Oluwa, ati ninu ile ọba, ati ti awọn ijoye, o si fi fun ọba Assiria: ṣugbọn kò ràn a lọwọ.
22. Ati li akokò ipọnju rẹ̀, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa. Eyi ni Ahasi, ọba.