11. Ussiah si li ẹgbẹ́-ogun awọn enia ti njagun, ti ima lọ ijagun li ẹgbẹgbẹ gẹgẹ bi iye kikà wọn, nipa ọwọ Jegieli, akọwe, ati Maaseiah, olori labẹ ọwọ Hananiah, ọkan ninu awọn olori ogun ọba.
12. Gbogbo iye olori awọn baba, alagbara akọni ogun jẹ ẹgbẹtala.
13. Ati li ọwọ wọn li agbara ogun kan wà, ọkẹ mẹdogun enia o le ẹ̃dẹgbãrin ti o mura, ti nfi àgbara nla jagun, lati ràn ọba lọwọ si ọta.
14. Ussiah si pesè fun wọn, já gbogbo ogun na, asà ati ọ̀kọ, ati akoro, ati ohun ihamọra-ọrùn, ati ọrun titi de okuta kànakàna.
15. O si ṣe ohun ẹrọ-ijagun ni Jerusalemu, ihumọ ọlọgbọ́n enia, lati wà lori ile-iṣọ, ati lori igun odi, lati fi tafa, ati lati fi sọ okuta nla. Orukọ rẹ̀ si tàn lọ jìnajina, nitoriti a ṣe iranlọwọ iyanu fun u, titi o fi li agbara.
16. Ṣugbọn nigbati o li agbara tan, ọkàn rẹ̀ gbé ga soke si iparun; nitoriti o ṣe irekọja si Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si lọ sinu tempili Oluwa, lati sun turari lori pẹpẹ turari.
17. Asariah, alufa si wọle tọ̀ ọ lọ ati ọgọrin alufa Oluwa pẹlu rẹ̀, awọn alagbara,
18. Nwọn si tako Ussiah ọba, nwọn si wi fun u pe, Ki iṣe tirẹ, Ussiah, lati sun turari fun Oluwa, bikòṣe ti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ti a yà si mimọ́ lati sun turari: jade kuro ni ibi mimọ́; nitoriti iwọ ti dẹṣẹ; bẹ̃ni kì yio ṣe fun ọlá rẹ lati ọdọ Oluwa Ọlọrun.
19. Nigbana ni Ussiah binu, awo-turari si mbẹ lọwọ rẹ̀ lati sun turari: ati nigbati o binu si awọn alufa, ẹ̀tẹ yọ ni iwaju rẹ̀, loju awọn alufa ni ile Oluwa lẹba pẹpẹ turari.
20. Ati Asariah, olori alufa, ati gbogbo awọn alufa wò o, si kiyesi i, o dẹtẹ ni iwaju rẹ̀, nwọn si tì i jade kuro nibẹ, nitõtọ, on tikararẹ̀ yara pẹlu lati jade, nitoriti Oluwa ti lù u.
21. Ussiah ọba, si di adẹ̀tẹ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile àrun, nitori adẹtẹ ni iṣe, nitoriti a ké e kuro ninu ile Oluwa: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si wà lori ile ọba, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na,
22. Ati iyokù iṣe Ussiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin ni Isaiah woli, ọmọ Amosi, kọ.
23. Bẹ̃ni Ussiah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni oko ìsinkú ti iṣe ti awọn ọba; nitoriti nwọn wipe, Adẹtẹ li on: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.