Ati Asariah, olori alufa, ati gbogbo awọn alufa wò o, si kiyesi i, o dẹtẹ ni iwaju rẹ̀, nwọn si tì i jade kuro nibẹ, nitõtọ, on tikararẹ̀ yara pẹlu lati jade, nitoriti Oluwa ti lù u.