1. NIGBANA ni gbogbo enia Juda mu Ussiah ti iṣe ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀, Amasiah.
2. On kọ́ Elotu, o si mu u pada fun Juda; lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀.
3. Ẹni ọdun mẹrindilogun ni Ussiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jekoliah ti Jerusalemu.
4. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀, Amasiah, ti ṣe.
5. O si wá Ọlọrun li ọjọ Sekariah, ẹniti o li oye ninu iran Ọlọrun: niwọn ọjọ ti o wá Oluwa, Ọlọrun si mu u ṣe rere.
6. O si jade lọ, o si ba awọn ara Filistia jagun, o si wó odi Gati ati odi Jabne ati odi Aṣdodu, o si kọ́ ilu wọnni ni Aṣdodu, ati lãrin awọn ara Filistia.
7. Ọlọrun si ràn a lọwọ si awọn ara Filistia, ati si awọn ara Arabia, ti ngbe ni Gur-Baali, ati awọn ara Mehuni.
8. Awọn ara Ammoni ta Ussiah li ọrẹ: orukọ rẹ̀ si tàn lọ kakiri titi de atiwọ Egipti; nitoriti o mu ara rẹ̀ le gidigidi.
9. Ussiah si kọ́ ile iṣọ ni Jerusalemu, nibi ẹnu-bode Igun, ati nibi ẹnu-bode Afonifoji, ati nibi iṣẹpo-odi, o si mu wọn le.
10. O kọ́ ile iṣọ li aginju pẹlu, o si wà kanga pupọ: nitoriti o li ẹran-ọsin pipọ, ati ni ilẹ isalẹ, ati ni pẹ̀tẹlẹ: o ni àgbẹ ati awọn olutọju àjara lori òke nla, ati lori Karmeli: nitoriti o fẹran àgbẹ-ṣiṣe.
11. Ussiah si li ẹgbẹ́-ogun awọn enia ti njagun, ti ima lọ ijagun li ẹgbẹgbẹ gẹgẹ bi iye kikà wọn, nipa ọwọ Jegieli, akọwe, ati Maaseiah, olori labẹ ọwọ Hananiah, ọkan ninu awọn olori ogun ọba.