O kọ́ ile iṣọ li aginju pẹlu, o si wà kanga pupọ: nitoriti o li ẹran-ọsin pipọ, ati ni ilẹ isalẹ, ati ni pẹ̀tẹlẹ: o ni àgbẹ ati awọn olutọju àjara lori òke nla, ati lori Karmeli: nitoriti o fẹran àgbẹ-ṣiṣe.