2. Kro 24:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori Ataliah, obinrin buburu nì ati awọn ọmọ rẹ ti fọ ile Ọlọrun; ati pẹlu gbogbo ohun mimọ́ ile Oluwa ni nwọn fi ṣe ìsin fun Baalimu.

8. Ọba si paṣẹ, nwọn si kàn apoti kan, nwọn si fi si ita li ẹnu-ọ̀na ile Oluwa.

9. Nwọn si kede ni Juda ati Jerusalemu, lati mu owo ofin fun Oluwa wá, ti Mose iranṣẹ Ọlọrun, fi le Israeli lori li aginju.

10. Gbogbo awọn ijoye ati gbogbo awọn enia si yọ̀, nwọn si mu wá, nwọn fi sinu apoti na, titi o fi kún.

11. O si ṣe, nigbati akokò de lati mu apoti na wá sọdọ olutọju iṣẹ ọba nipa ọwọ awọn ọmọ Lefi, nigbati nwọn si ri pe, owo pọ̀, akọwe ọba ati olori ninu awọn alufa a wá, nwọn a si dà apoti na, nwọn a mu u, nwọn a si tun mu u pada lọ si ipò rẹ̀. Bayi ni nwọn nṣe li ojojumọ, nwọn si kó owo jọ li ọ̀pọlọpọ.

2. Kro 24