10. Ṣugbọn nigbati Ataliah, iya Ahasiah, ri pe ọmọ on kú, o dide o si run gbogbo iru ọmọ ijọba ile Judah.
11. Ṣugbọn Jehoṣabeati, ọmọbinrin ọba, mu Joaṣi, ọmọ Ahasiah, o ji i kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa, o fi on ati olutọ rẹ̀ sinu yẹwu Ibusùn. Bẹ̃ni Jehoṣabeati, ọmọbinrin Jehoramu ọba, aya Jehoiada, alufa, (nitori arabinrin Ahasiah li on) o pa a mọ́ kuro lọdọ Ataliah ki o má ba pa a.
12. O si wà pẹlu wọn ni pipamọ́ ninu ile Ọlọrun li ọdun mẹfa: Ataliah si jọba lori ilẹ na.