36. O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi.
37. Nigbana ni Elieseri ọmọ Dodafah ti Mareṣa sọtẹlẹ si Jehoṣafati wipe, Nitori ti iwọ ti dá ara rẹ pọ̀ mọ Ahasiah, Oluwa ti ba iṣẹ rẹ jẹ. Awọn ọkọ̀ na si fọ́, nwọn kò si le lọ si Tarṣiṣi.