2. Kro 2:17-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Solomoni si kaye gbogbo awọn ajeji ọkunrin ti o wà ni ilẹ Israeli, gẹgẹ bi kikà ti Dafidi, baba rẹ̀ ti kà wọn; a si ri pe, nwọn jẹ ọkẹ-mẹjọ o di-egbejilelọgbọ̀n.

18. O si yàn ẹgbã marundilogoji ninu wọn lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ṣe aké-okuta li ori òke, ati egbejidilogun alabojuto lati kó awọn enia ṣiṣẹ.

2. Kro 2