14. Wọnyi ni iye wọn gẹgẹ bi ile baba wọn: Ninu Juda, awọn olori ẹgbẹgbẹrun; Adna, olori, ati pẹlu rẹ̀, ọkẹ́ mẹ̃dogun alagbara akọni ọkunrin.
15. Ati atẹle rẹ̀ ni Jehohanani olori, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹrinla ọkunrin.
16. Ati atẹle rẹ̀ ni Amasiah, ọmọ Sikri, ti o fi tinutinu fi ara rẹ̀ fun Oluwa; ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹwa alagbara akọni ọkunrin.
17. Ati ninu Benjamini; Eliada alagbara akọni ọkunrin, ati pẹlu rẹ̀ awọn enia ti nfi ọrun ati apata hamọra, ọkẹ mẹwa.
18. Ati atẹle rẹ̀ ni Jehosabadi, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹsan, ti o mura silẹ de ogun.
19. Wọnyi nduro tì ọba, li aika awọn ti ọba fi sinu ilu olodi ni gbogbo Juda.