10. Ẹ̀ru Oluwa si ba gbogbo ijọba ilẹ na, ti o wà yikakiri Juda, tobẹ̃ ti nwọn kò ba Jehoṣafati jagun kan.
11. Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun.
12. Jehoṣafati si npọ̀ si i gidigidi: o si kọ́ ile olodi, ati ilu iṣura ni Juda.
13. O si ni iṣura pupọ ni ilu Juda; ati awọn jagunjagun, awọn alagbara akọni ọkunrin ti o wà ni Jerusalemu.
14. Wọnyi ni iye wọn gẹgẹ bi ile baba wọn: Ninu Juda, awọn olori ẹgbẹgbẹrun; Adna, olori, ati pẹlu rẹ̀, ọkẹ́ mẹ̃dogun alagbara akọni ọkunrin.
15. Ati atẹle rẹ̀ ni Jehohanani olori, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹrinla ọkunrin.
16. Ati atẹle rẹ̀ ni Amasiah, ọmọ Sikri, ti o fi tinutinu fi ara rẹ̀ fun Oluwa; ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹwa alagbara akọni ọkunrin.
17. Ati ninu Benjamini; Eliada alagbara akọni ọkunrin, ati pẹlu rẹ̀ awọn enia ti nfi ọrun ati apata hamọra, ọkẹ mẹwa.
18. Ati atẹle rẹ̀ ni Jehosabadi, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹsan, ti o mura silẹ de ogun.
19. Wọnyi nduro tì ọba, li aika awọn ti ọba fi sinu ilu olodi ni gbogbo Juda.