10. Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú.
11. Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na.
12. Nitorina, bi mo tilẹ ti kọwe si nyin, emi kò kọ ọ nitori ẹniti o ṣe ohun buburu na, tabi nitori ẹniti a fi ohun buburu na ṣe, ṣugbọn ki aniyan nyin nitori wa le farahan niwaju Ọlọrun.
13. Nitorina a ti fi itunu nyin tù wa ninu; ati ni itunu wa a yọ̀ gidigidi nitori ayọ̀ Titu, nitori lati ọdọ gbogbo nyin li a ti tu ẹmi rẹ̀ lara.