1. NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun.
2. Ẹ gbà wa tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹni, a kò bà ẹnikẹni jẹ, a kò rẹ́ ẹnikẹni jẹ.
3. Emi kò sọ eyi lati da nyin lẹbi: nitori mo ti wi ṣãjú pe, ẹnyin wà li ọkàn wa ki a le jumọ kú, ati ki a le jumọ wà lãye.