1. ẸNYIN iba gbà mi diẹ ninu wère mi: ati nitotọ, ẹ gbà mi.
2. Nitoripe emi njowú lori nyin niti owú ẹni ìwa-bi-Ọlọrun: nitoriti mo ti fi nyin fun ọkọ kan, ki emi ki o le mu nyin wá bi wundia ti o mọ́ sọdọ Kristi.
3. Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi.